IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE TONIKI KEJIDINLOGOJI (38 WEEK, 2026) - SISO ÌJÉRÍ RẸ

IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE TONIKI KEJIDINLOGOJI (38 WEEK, 2026) - SISO ÌJÉRÍ RẸ

IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE TONIKI KEJIDINLOGOJI - SISO ÌJÉRÍ RẸ

IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI

OSE/ TONIKI KEJIDINLOGOJI

AKÓRÍ ỆKÓ: SISO ÌJÉRÍ RẸ 

ÈSÈ WÚRÀ: ORIN DAFIDI 105:1-8

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀: Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀: Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa: ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
8 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,

Àfojúsùn: Láti mọ pé nipa ijéri a lè jere opọ ọkàn fun Kristi.

İfáara:

Ìjeri ję irinșẹ tí mí Mímọ ú lò láti fi ìfé Olorun ru okan àwọn ènìyàn soke. Ijeri je ona ti o lagbara ti a le fi wasu ihinrere, nitori o je ona fun wa lati so itan iriri wa. Kii se lati fi han pe a tobi sugbon lati fi titobi kristi han ninu wa. İtàn ìgbàlà wa je ohun ti o ni agbara ti a le lo ni orisirisi ona.


Àwọn Kókó fún Ìjórò:

1. O ko lè fún eniyan ni ohun tí o ko ní." Şàlàyé eleyi, ni ibamu pelu eko wa. 2 Kor. 8:12; Johanu 3:27

2. Ni kukuru, se alaye awọn ìlànà ti a le tele lati pin ijeri wa. Orin Dafidi 66:16

a. Ko gbodo gba akoko, o si gbodo ye awon eniyan. İşe 4:13,23

b. Má se so asodun.

c. Má șe jsoo gegebi eni to fe ran Olorun lowo.

d. Fi ìhìnrere hàn ni kedere ninu ijeri re.

e. Máșe so ijeri di awada.

3. Kini anfààní ti o wa ninu ijerì? Josua 4:5-7; Orin Dafidi 71:15-16; 145:2-4; 1 Kor. 11:1


Oro Ikadi:

Ìjérì jẹ ìtàn bi Olorun se nsise nínú igbésí-ayé wa. Eyi je orisirisi ona ti Olorun gba ba wa pade ninu irin wa pelu Re. Sugbon a ko gbodo gbagbe wipe fifi ogo Olurun han ati fifa awon eniyan wa sodo Olorun ni afojusun wa. Elomiran le di eni igbala nipa gbigbo bi a ti gba o la. E je ki gbiyanju lati maa so ohun rere ti kristi se fun wa fun gbogbo eniyan.


Èsè Àkósórí: Orin Dafidi 105:1 E fi ope fun Oluwa, e pe oruko Re, e fi ise Re han ninu awon eniyan.


KOKO ORO: Iwo yio je segun ni o nípasę oro ijęrì rẹ.

Previous Post Next Post