IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE YI, OSE KERINDILOGOJI (36) TI ODUN 2026 - GBIGBE IHAMORA ÌMÓLỆ WO
IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI
OSE/TONIIKI KERINDILOGOJI
AKÓRÍ EKO: GBIGBE IHAMORA ÌMÓLỆ WO
ESÈ WÚRÀ: RÓÒMÙ 13:11-14
11 Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ.
12 Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀.
13 Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara.
14 Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
ÀFOJÚSÙN: Ki a maa gbára le agbara Olorun, kì í șe ti eran ara.
İFÁARA:
Gbigbe iharamora Ìmólę wo gégé bí a ti rii ninu Róòmù 13:12 je afiwe taara si igbe-aye iwa mimo ati gbigbe igbe-aye ti o fi imole Olorun han; eyi yoo farahan ni kiko okunkun ati ise owo re sile. Eyi je ona ti o dara lati maa gbe igbe aye ti o ba ife Olorun mu ati ki igbe aye wa maa fi otito, ife ati igbagbo han. Eyi gbodo je ojuse wa lojojumo, nipa adura gbigba, bibeli kika ati ipejopo awon ara.
ÀWỌN KÓKÓ FÚN ÌJORÒ:
1. Wiwò ihamora ìmólę tumo si gbigbe Jesu Kristi wo. Şàlàyé. Róòmù 13:12; Galatia 3:27; Efesu 4:24.
2. Ihámora imole nse apejuwe aabo ati agbara ti nfi iwa mimo ati ododo Olorun han. Salaye. Orin Dafidi 91:1-2; Isa. 4:5
3. Awon ona wo ni a șe lè gbe ihamora ìmólę wo? Kolose 3:12-14; Róòmù 12:2; Efesu 4:22-24; Mátíù 5:14-16
ORO IKADI:
Wiwo lhamora ìmólẹ túmọ sí gbigbe Jesu Kristi fúnra Rę wo. Awon to ba dabii Jesu ninu iwa ati ise ni a le pe ni eni to gbe ihamora imole wo. Ìmólę yìí ni ń dáàbòbòwá lówo agbára òkùnkùn ati idojuko agbara aye.
ÈSÈ ÀKÓSÓRÍ: Róòmù 13:12 Oru bukoja tan, ile si fere mo nitorina e je ki a bo ara okunkun sile, ki a si gbe ihamora imole wo.
KOKO ORO: Okunkun ko le bori imole.