EKO BIBELI OLOSOOSE TI IJO ELETO (METHODIST) FUN TI OSE YI EKO KARUN DIN LOGOJI (35WEEK, 2026) - IBASEPO PELU AWON TI KO NI OYAYA
JIJE OMOLEHIN 2026
EKO KARUN DIN LOGOJI (35)
AKORI ORO: IBASEPO PELU AWON TI KO NI OYAYA
ESE BIBELI KIKA: JOHANU 12:1-7
1.Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú.
2. Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.
3. Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
4. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé,
5. “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?”
6. Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
7. Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi.
IFAARA:
Awọn alaini oyaya itagbangba ję awon eniyan ti o sa ba maa n dara de ohun atinuwa won. Wọn maa n ni arojinle nipa ohun ti won gbo, won si maa n dawa ni awon nikan. Ibadore won maa n jinle, won si ni ogbo atinuda.
Màríà, arábìnrin Màtá àti Lásárù, ni a şàpèjúwe gégé bí ẹni tí ó ni arojinlè gan-an, tí ó yàn láti fi ikunra olòórùn dídùn kun ęsè Jésù; Ìmoore, ifé àti ifọkànsìn ati ihuwasi re bá afiwé isesi awon alaini oyaya itagbangba mu. Nipa akiyesi, a sakiyesi wipe opọlọpọ awọn onişe onà nla ni agbaye, awọn onkowe, ati awọn olorin ni won abuda aini oyaya itagbangba. Ninu didawa ati ironujinle ni agbara won wa. Wọn saba maa n tayo ninu işaro Bibeli nitori pe o ni afijo pelu iru eniyan ti won je.
AWON IBEERE ATI IJIRORO
1. "Pupo awon alaini oyaya itagbangba maa n ni ironu to jinle" Jiroro. Luuku 10:38-42; Johanu 12:1-3
2. Jiroro lorii bi awọn alaini oyaya itagbangba şe le kopa ti o ni itumo si ọgbọn ijinle ninu Ijo loni? Tímótiu kinni 2:15, İşe Awon Aposteli 17:11-12
3. "Pupo awon alaini oyaya itagbangba ni a wọn karamasiki dida yanju isoro, dida ipinnu se ati awọn akitiyan adaşe" Jiroro
4. Ni iwoye tire, bawo ni awọn amuye to tinu abuda yi wa fun anfani Ijo lode oni?
ORO IKADI:
Olórun dá wa pelu ipele oríşiríşi agbára, àìlagbara, àti abuda. Nigbati awon alaini oyaya itagbangba ba fi igbesi aye won silę lekunrere si abe akoso Jesu Kristi Oluwa, wọn le e je afadura jagun nla, awọn agbani niyanju, ati olukoni.
Yálà eniyan ni oyaya tabi ko ni oyaya, Kristeni nílo láti rántí wipé èbùn láti òdò Olórun ni abuda ohun, o si gbodo lò fún ògo Rè.
ESE AKOSORI: Luku 10:42 "Şugbọn ohun kan ni a ko le e se alaini, Maria si ti yan ipa rere naa ti a ko le e gba lọwọ rẹ"