JIJE OMOLEHIN, EKO BIBELI OLOSOOSE 2026 TI IJO ELETO (METHODIST) TI OSE YI, EKO KERIN LE LOGBON (34 WEEK, 2026) - ÌBÁDÓRÈÉ: TANI, KINNIATI BAWONINUORESISE ESISE
JIJE OMOLEHIN 2026
EKO KERIN LE LOGBON (34)
AKORI EKO: ÌBÁDÓRÈÉ: TANI, KINNIATI BAWONINUORESISE ESISE
ESE BIBELI KIKA: 1 SAMUELI 18:1-4, 19:1-6
IFAARA
Pelú ìwòye Kristeni, ìbádórèé ni a lè wò gégé bí ipa kan pàtàkì ní ìgbésí ayé, tí ó fidímúlè nínú ìfé Olórun tí a sì gbé e kale fún ìtìléyìn ti o dan manran, idàgbàsókè, àti ìgbara-eni-niyanju. Ó jé ìbáșepò tí ó yẹ kí a gbélewon lorii ajopin ìgbàgbó, ifé, àti ifé-ọkàn láti mu ara wa súnmó Olórun kí a sì mú ète wa șẹ. Ìbádórèé laarin Dáfídì àti Jónátánì gégé bí a ti șàpèjúwe rè nínú àwọn ayoka Bibeli wa ni a ri gégé bíàpẹẹrẹ ńláňlà fun ìdúróșinşin àti ìfé àìmotara-eni-nìkan. Pelu ikóriíra ti ó wà láàárín Dáfídì àti bàbá Jónátánì, síbè ajoose wọn sì lágbára, kódà dé ibi tí Jónátánì fi dáàbò bo Dáfídì lówó ète ìpànìyàn bàbá rè.
Nitooto, ìbádórèé Kristiani ni a le ri bii afihan ifę Olorun, ati ọna lati şe iwuri fun'ra wa lati gbe ara wa soke.
AWON IBEERE ATI IJIRORO
1. Ìbádórèé Kristeni tòótó şàfihan ìfé Kristi, èyí tí ó nii se pelu ifara-eni-ji àti àìmotara-eni-nikan" Jíròrò.
2. Bawo ni eniyan şe lee kiyesara daadaa nipa yiyan awọn orę lode oni? Òwe 12:26; Korinti keji 6:14-17; Òwe 22:24-25
3. Awọn orẹ otito a maa sunmo eni ju ębi lọ; wọn maa n fi aaye gba wa nigba ipenija, wọn yio si ba wa yọ nigbati ohun gbogbo ba se deedee" Jiroro lori eleyi ni ibamu pelu iriri ti ara re. Oniwaasu 4:11-12
4. Jiroro lorii bi ìbádórèé ti o dara ju pẹlu Olorun şe lee ran ibadore laarin arakunrin/arabirin lowo. Johanu 15:12-15, Orin Dafidi 25:14, Jakobu 2:23-24
ORO IKADI
Igbe aye wa loni n se lodi si ibadore tooto laarin awon Kristeni, nitori pe o ferę ję wipe gbogbo eniyan ni işe wọn ko fi aaye gba lati r'aye fun elomiran. Sugbon, sibęsibę a le lo akoko perete yi lati ni ibadore to jinle, fun igbara-eni-niyanju ati iranlowo. Wọn yoo fi ayo fun wa, ati atileyin fun ipinnu wa, lati tęsiwaju ni irin-ajo igbesi aye wa. Oniwaasu 4:9-10
ESE AKOSORI:
Owe 12:26 "Olódodo eniyan maa n sora lati dórèé sugbon ona awon eniyan buburu n mu won sina"
