JIJE OMOLEHIN OLOSOOSE (METHODIST) EKO KETA DIN LOGOJI (37 WEEK, 2026) - IBASEPO PELU AWON ALAIGBAGBỌ

JIJE OMOLEHIN OLOSOOSE (METHODIST) TI OSE YI EKO KETA DIN LOGOJI (37 WEEK, 2026)  - IBASEPO PELU AWON ALAIGBAGBỌ

JIJE OMOLEHIN OLOSOOSE (METHODIST) EKO KETA DIN LOGOJI (37 WEEK, 2026)  - IBASEPO PELU AWON ALAIGBAGBỌ

EKO KETA DIN LOGOJI (37)

AKORI EKO: IBASEPO PELU AWON ALAIGBAGBỌ

ESE BIBELI KIKA: KORINTI KEJI 9:16-23

1 Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 
2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 
3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
4 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 
5 “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 
6 Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
7 Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi.


IFAARA

Gégé bí Kristeni, ó dájú wipé a ní àwọn aláìgbàgbó gégé bí akẹgbẹ wa níbi işé, gege bi ìbátan wa, àwọn alábágbele wa, àti awon olùkó wa. Otito ni wipe a ko pe wa lati sa kuro ninu aye şugbọn a ko gbodo darawa po mo aye.

A paa laşẹ fún àwọn Kristeni lati nífèé àwọn aládùúgbò wọn, èyí ti ko yọ àwọn aláìgbàgbó sile, kí wọn sì fi inú rere àti ibòwòfun bá wọn lò. ìbáșepò pèlú àwọn aláìgbàgbó leè jasi à fààní ìjeri fun Kristi. Sugbon bi a şe n şe eyi, a gbodo kiyesara nipa biba alaigbagbo se wole-wode. Korinti keji 6:14.


AWON IBEERE ATI IJIRORO

1. Jiroro lori bawo ni igbesi aye oniwa-bi-Olorun ati iwa rere şe n waasu fun awon alaigbagbo ju oro wa lọ? Matiu 5:13,16, Peteru kinni 3:1-2

2. Báwo ni Kristeni șe leè fi ógbón, òye ati ironú jinlè ni ibasepo pelu alaigbagbo? Kólose 4:5-6, Owe 11:30

3. "Ibaşepo pẹlu awọn alaigbagbo nilo adura, itoni ati itosona Olorun" Jiroro. Jeremaya 33:3, Orin Dafidi 32:8, 25:8-9

4. So diẹ ninu awọn igbese oniwa-bi-Olorun ti o see mulo fun ipolongo Kristi pẹlu awọn elomiiran nigbati ayee rẹ ba și silẹ. Máàkù 16:15-16, Tímótìu keji 4:5, Róòmù 12:1-2


ORO IKADI

A pe awọn Kristiani lati ję iyo aiye ati imolę ni agbaye; ki a ni ibasepo pèlú àwọn aláìgbàgbó ní ònà ìfé àti ibowòfun, pelu ikiyesara, ki a ma baa subu.

Gégé bí Kristeni, a gbódò máa sa ipá wa nígbà gbogbo láti gbé ìgbésí ayé tíń bu olá fún Olórun, kí a sì yera fún èsè.


ĘSĘ AKOSORI: Kólósè 4:5 "E je ologbon ni ti bi e ti n se pelu awon ti n be lode, ki e si mase şi anfani ti e ba ni lo"

Previous Post Next Post