JIJE OMOLEHIN OLOSOOSE 2026 (METHODIST) TI OSE YI EKO KERIN DIN LOGOJI (36 WEEK, 2026) - IBASEPO PELU AWON TO NI OYAYA
JIJE OMOLEHIN 2026
EKO KERIN DIN LOGOJI (36)
AKORI EKO: IBASEPO PELU AWON TO NI OYAYA
ESE BIBELI KΙΚΑ: İŞE AWON APOSTELI 13:1-5, 12-13
1 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu.
2 Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”
3 Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
4 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi.
5 Nígbà ti wọ́n sì wà ni Salami, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Sinagọgu àwọn Júù. Johanu náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.
12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.
13 Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.
IFAARA
Nínú àwọn ẹsẹ ìwé Mímọ ti a ka wònyí ni a ti lè șe àkójọ bí Olórun şe gbe agbara wọ Póòlù àti Bánábà, tí a sì yà wọn sótò fún işé itankale ihinrere ńlá àti işé iranse. Abuda oloyaya ita gbangb ni won jé, lati le e şe işe naa ti a yan won si daradara.
Awọn oloyaya ita gbangba ni awọn ti o yara lati ni ibasepo, ibakegbe tabi ibadore pelu ara ita. Bi oyaya itagbangba eniyan şe po si, beeni iwoye eniyan nipa igboro aye yio tip o to. Inu won maa n dun lati wa ni ayika awon elomiran.
Níwòn bí ó ti je pe a gbodo kéde ìhìnrere pèlú ìdùnnú, eyi ti awon oloyaya ni abuda re, o rorun fun awon to ni oyaya lati kéde ìhìnrere, ni ifowosowopo pèlú àwọn ẹlòmíràn àti láti mú àwùjọ dàgbà. Awon oloyaya je Ajihinrere, nigbati awọn ti ko ni oyaya maa n tayo ninu ise Oluso-Aguntan ati sisoni-di-omoehin.
AWON IBEERE ATI IJIRORO
1. Jiroro lorii itenumo wipe oloyaya ita gbangba ni okun ti o le ru ife okan si Kristi soke nibikibi. İşe Awon Aposteli 8:4-8, 13:2-3,16:13-15.
2. Awon oloyaya ita gbangba wulo ninu isopo, jije alagbawi ati agbateru ibaraenisoro ninu Ijo lode oni. Jiroro. Johanu 1:43-45
3. "Dafidi yàn láti dojú kọ Gòláyátì nítorí pé ó rí àìfààní láti şe afihàn agbára Olórun" Jíròrò lorii bí èyí şe şàpęẹrẹ Dáfídì gégé bíi oloyaya ita gbangba. 1Sam.17:12-15,20-28
4. Jiroro lori idi ti a fi dupe lowo Olorun fun orisirisi awọn eda eniyan ati ooreofe ti a fun won ninu molebi Olorun. Korinti kinni12:12-20, Roomu 12:4-8
ORO IKADI
Otito ni wipe Olorun şeda wa yato ki a le jumo şişe lati şe awọn ohun nla fun Kristi. Je ki a dekun igbiyanju lati yi awọn oloyaya ita gbangba pada si awọn alaini oloyaya ita gbangba, ati ni idakeji. E ki a tewo gba ara wa nigbagbogbo bi a ti riati gegebi iseda Olorun. A gbódò sapá láti lo èbùn àti agbára wa fún ògo Olórun bí a tíń pe ara wa níjà láti fún ara wa lókun ninu ipo ailagbara enikookan wa.
ESĘ AKOSORI:
Róòmù 12:6 "Nje bi awa si ti n ri otooto ebun gba gegebi oore-ofę ti a fi fun wa, bi
