IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE OGOJI (40 WEEK, 2026) - JESU NI IPILE WA
OSE /TONIIKI OGOJI
AKÓRÍ ÈKÓ: JESU NI IPILE WA
ÈSÈ WÚRÀ: MÁTÍÙ 21:33-44
33 “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. 34 Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.
35 “Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta. 36 Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. 37 Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’ 38 “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’ 39 Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.
40 “Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?”
41 Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”
42 Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?
43 “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá. 44 Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
Afojúsùn: Láti mọ pé Kristi ni ìpilę igbàgbó wa.
İfáara:
Ninu iwe Matiu 21:33-44 Jesu lo àpeẹrẹ ogbà àjàrà láti fi hàn pé Ón ni Apáta Igunle. Okuta se pataki ninu ile; on ni yio mu ki ile duro daradara. Ninu eko yi, ao se akiyesi bi kristi se mu ife Olorun yi se ninu ohun ti a gbagbo ati ninu aye wa. Eyi fi pataki ipinnu Olorun han ati ijiya to wa ninu kiko ipinnu yi sile.
Àwọn Kókó fún Ìjirorò:
1.(a) Kíni o tumo pipe Jesu ni Okuta Igun ile? Mátíù 21:42b
(b) Báwo ni ìmò yìí șe nse atona igbe-aye wa ati ipinnu wa lojoojúmo?
2. (a) Tani Jesu n so nipa re ninu owe yi (Matiu 21:33-44)? Kini idi ti owe yi fi se pataki?
(b) Kini ogba ajara tumo si?
3. Bi Olorun se nran awon iranse lore-koore se afihan pe Olorun fe ironupiwada ati ore-ofe.
Oro Ikadi:
Jesu ni ìpilę igbésí-ayé wa, a gbodo gba eyi gbo. Ohun ni ipinle aye wa, olutoju wa ni igba isoro ati pe On ni on ran wa lowo lati ni oye ife Olorun ati ore-ofe. A gbodo fi ara wa ji si gbigbe aye sori ipile daradara yi.
Èsè Àkósórí: Mátíù 21:42b Okuta ti awon omole ko sile on na li o si di pataki igun ile; eyi ni ise Oluwa, o si je iyanu li oju wa.
KOKO ORO: Kristi ni Ipile wa.