IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE YI, OSE KOKANDINLOGOJI (39 WEEK, 2026) - ORÚKO JESU
OSE/ TONIIKI KOKANDINLOGOJI
AKÓRÍ ĘKI: ORÚKO JESU
ÈSÈ WÚRÀ: FILIPPI 2:6-11
Àfojúsùn: Láti gbé igbagbo wa sórí agbára orúkọ Jesu fún ohun gbogbo.
İfáàra:
Oruko 'Jesu' túmọ sí “Olorun ń gbàlà.” Orúkọ yìí ni agbára àtì gbàlà. Oruko yi fi ipa Jesu han ninu ise igbala. A tun npeE ni Imanueli (Olorun wa pelu wa), Odo Aguntan Olorun ati Oba awon Ju. Awon oruko wonyi nse apeere ise ati ilepa Jesu ninu aye.
Àwọn Kókó fún Ìjiròro:
1. Kíni pàtàkì orúkọ ati iwulo re ní ayé òde òní? Òwe 22:1; Gen. 32:28; Johanu 1:12; Exodu 20:7
2. Jesu n gbàlà ti O si yí ìgbésí-ayé padà. Bawo ni eyi se je otito? Ie 9:1-9; Gal. 3:26; Johanu 3:16; Johanu 4:42
3. A fún Jesu ní orúkọ tó ga jù gbogbo orúkọ lọ (filipi 2;5-9). àlàyé ìrírí rę pẹlú agbára orúkọ yìí.
Oro Ikadi:
Bi a ba ri oruko kan ti o ni agbara julo, ti o si wulo nigbogbo ona, orúkọ Jesu ni. Awon ti ko tile gbagbo ninu Re, maa npe oruko Re nigba isoro. Olorun ran Jesu wa fun idi pataki; oruko Jesu si n se afihan ise pataki yi (Matiu 1:21). Bi Joshua ninu majemu laelae se dari awon omo Isreli lati bori awon ara Kenaani, bee gege ni Jesu ninu Majemu Titun dari gbogbo eniyan lati bori ese ati Esu.