IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE YI, OSE KARUNDINLOGOJI (35) TI ODUN 2026 - TANI JESU SI O?
ΕΚΟ: ΤΟΝΙΙKI KARUNDINLOGOJI
AKORI EKO: TANI JESU SI O?
ESE WURA: MATIU 16:13-28
AFOJUSUN: Ki a le mo iru eni ti Jesu je si wa.
IFAARA:
Nigba ti a ba bi o wipe tani Jésù je si o, orisirisi ero ni yio maa wa si okan wa. Eyi nri bee nitori wipe Jesu je ohun ti o yato si opolopo eniyan lorisirisi ona. Eyi fi han kedere nigbati Jesu nbi awon omo lehin wipe kini ohun ti awon eniyan nfi ohun pe. Ohun ti won so fihan wipe orisirisi ona ti o yato si ara won nri Jesu. Ki enikeni ki o to le ni oye Jesu, eran ara gbodo teriba fun Emi Olorun. Idi ti a fi n jijakadi lati ni oye eni ti Jesu nse ni wipe, a ko tii bori eran ara.
IBEERE ATI IJIRORO:
1. Tani Jesu Kristi nse? Matiu 16:16, 1Joh 4:9, Ise 4:11-12, Filipi 2: 8-11
2. Bawo ni ara se le di wa lowo lati ni oye eniti kristi nse? Matiu 16: 17, Galatia 5:17, Joh 3: 5-6, Romu 8:5
3. Gegebi eni ti o gbagbo ninu kristi, kini idahun re yio je nigbati alaigbagbo ba bi o wipe, "tani Jesu si o"?
ORO IKADI
Gbogbo awon ti o mo Olorun won yio gbe okan won leE. Olorun kii ko enikeni tio gbeke leE sile. Jesu ni Oluwa wa ati Olugbala araye (Filipi 2: 10-11). O je ohun iyalenu wipe opo eniyan mo Jesu gegebi Olugbala sugbon won ko gba A gege bi Oluwa won. Bi Jesu ba je Oluwa re, o ni lati fun-Un ni aye lati ni ase lori aye re. Nje Jesu ni Oluwa aye re bi? Tani Jesu si o?
ESE AKOSORI:
Matiu 16:16 Simoni Peteru si dahun, wipe, kiristi, omo Olorun alaaye ni iwo ise.
