IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE KEJILELOGOJI (42 WEEK, 2026) - IBAGBEPO OLORUN

IJO ELETO NAIJIRIA, TONIIKI OJO ISIMI TI OSE   KEJILELOGOJI (42 WEEK, 2026) -  IBAGBEPO OLORUN


AKÓRÍ EKÓ:
IBAGBEPO OLORUN

ÈSÈ WÚRÀ: ÈXODU 33:12-16

12 Mose sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́n nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojúrere mi pẹ̀lú.’
13 Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́n, kí n sì le máa wá ojúrere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀-èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”
14 Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”
15 Nígbà náà ni, Mose wí fún un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má ṣe rán wa gòkè láti ìhín lọ. 
16 Báwo ni ẹnikẹ́ni yóò ṣe mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”


AFOJÚSÙN: Láti ję kó oye ati ogo ìwàlaaye Olorun ye wa.

İfáara:

Eko wa oni fi han bi Mósè se béèrè fún ìdaniloju ibagbepo Olorun bi o ti ndari awon omo Israeli. Ibi kika yi fi bi ibagbepo Olorun se se pataki to ninú aye wa. Iwalaaye Olorun n fun wa ni itunu, ìtósónà àti àmọràn. Eko yi yio se alaye ohun ti o tumo si lati ri iwalaaye Olorun ati gbigbe okan le iwalaaye Re.


Àwọn Kókó fún Ìjórò:

1. Kíni ó şẹlệ kí Mósè tó bẹ Olorun fun ìwàlaaye Rę? Bawo ni isele naa se fi oye ibi kika yi ye wa?

2. Kíló dé ti ó fi șe pàtàkì pé iwalaaye Olorun gbodo ma bá Ísrẹlì lọ? Èxodu 33:15-16; Orin Dafidi 114:7-8

3. Báwo ni a șe lè wá tabi mọ ìwàlaaye Olorun ninu aye wa ni ojojumo?


Oro Ikadi:

Nini iriri Iwalaaye Olorun je ohun ti o dara gidigidi ninu irin ajo emi wa. Ó í mú àlàáfĩà, ìtosọnà, àti ife wa ninu aye wa. Bii Mose, a le ni idaniloju wipe Olorun wa pelu wa ninu gbogbo ilakoja wa.


Èsè Àkósórí: Éxodu 33:14 On si wipe, oju mi yio ma ba o lo emi o si fun o ni isimi.


KOKO ORO: İwalaaye Olorun ni agbara wa.

Previous Post Next Post